Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 3:7-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ki oru na ki o yàgan; ki ohùn ayọ̀ kan ki o má ṣe wọnu rẹ̀ lọ.

8. Ki awọn ti ifi ọjọ gegun ki o fi i gegun, ti nwọn muratan lati rú Lefiatani soke.

9. Ki irawọ̀ ofẽfe ọjọ rẹ̀ ki o ṣokùnkun; ki o ma wá imọlẹ, ṣugbọn ki o má si, bẹ̃ni ki o má ṣe ri afẹmọjumọ́.

10. Nitoriti kò se ilẹkun inu iya mi, bẹ̃ni kó si pa ibinujẹ mọ́ kuro li oju mi.

11. Ẽṣe ti emi kò fi kú lati inu wá, tabi ti emi kò fi pin ẹmi nigbati mo ti inu jade wá?

12. Ẽṣe ti ẽkun wá pade mi, tabi ọmu ti emi o mu?

13. Njẹ! nisisiyi, emi iba ti dubulẹ̀ jẹ, emi a si dakẹ, emi iba ti sùn: njẹ emi iba ti simi!

14. Pẹlu awọn ọba ati igbimọ aiye, ti o mọle takete fun ara wọn.

15. Tabi pẹlu awọn ọmọ-alade ti o ni wura, ti nwọn si fi fadakà kún inu ile wọn.

16. Tabi bi ọlẹ̀ ti a sin, emi kì ba ti si; bi ọmọ iṣẹnu ti kò ri imọlẹ.

17. Nibẹ ni ẹni-buburu ṣiwọ iyọnilẹnu, nibẹ ẹni-ãrẹ̀ wà ninu isimi.

18. Nibẹ ni awọn ìgbekun simi pọ̀, nwọn kò si gbohùn amunisìn mọ́.

Ka pipe ipin Job 3