Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 3:20-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Nitori kili a ṣe fi imọlẹ fun otoṣi, ati ìye fun ọlọkàn kikoro.

21. Ti nwọn duro de ikú, ṣugbọn on kò wá, ti nwọn wàlẹ wá a jù fun iṣura ti a bò mọlẹ pamọ.

22. Ẹniti o yọ̀ gidigidi, ti inu wọn si dùn nigbati nwọn ba le wá isa-okú ri.

23. Kili a fi imọlẹ fun ẹniti ọ̀na rẹ̀ lumọ si, ti Ọlọrun si sọgba di mọ ká?

24. Nitoripe imi-ẹ̀dun mi ṣaju ki nto jẹun, ikerora mi si tú jade bi omi.

25. Nitoripe ohún na ti mo bẹ̀ru gidigidi li o de ba mi yi, ẹ̀ru ohun ti mo bà li o si de si mi yi.

26. Emi kò wà lailewu rí, bẹ̃li emi kò ni isimi, bẹ̃li emi kò ni ìfaiyabalẹ, asiwá-asibọ̀ iyọnu de.

Ka pipe ipin Job 3