Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 29:3-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Nigbati fitila rẹ̀ tàn si mi li ori, ati nipa imọlẹ rẹ̀ emi rìn ninu òkunkun ja.

4. Bi mo ti ri nigba ọ̀dọ́ mi, nigbati aṣiri Ọlọrun wà ninu agọ mi.

5. Nigbati Olodumare wà sibẹ pẹlu mi, nigbati awọn ọmọ mi wà yi mi ka.

6. Nigbati emi nfi ori-amọ wẹ̀ iṣisẹ mi, ati ti apata ntú iṣàn ororo jade fun mi wá.

7. Nigbati mo jade là arin ilu lọ si ẹnu ibode, nigbati mo tẹ ìtẹ mi ni igboro.

8. Nigbana ni awọn ọdọmọkunrin ri mi, nwọn si sapamọ́, awọn àgba dide duro.

9. Awọn ọmọ-alade dakẹ ọ̀rọ sisọ, nwọn a si fi ọwọ wọn le ẹnu.

10. Awọn ọlọla dakẹ, ahọn wọn si lẹmọ èrigi ẹnu wọn.

Ka pipe ipin Job 29