Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 29:10-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Awọn ọlọla dakẹ, ahọn wọn si lẹmọ èrigi ẹnu wọn.

11. Nitoripe eti gbọ́ ti emi, a si sure fun mi, oju si ri mi, on a jẹri mi.

12. Nitoriti mo gba talaka ti nsọkun, ati alainibaba, ati alaini oluranlọwọ.

13. Isure ẹniti o fẹrẹ iṣegbe wa si ori mi, emi si mu aiya opo kọrin fun ayọ̀.

14. Emi si mu ododo wọ̀, o si bò mi lara; idajọ mi dabi aṣọ igunwa ati ade ọba.

15. Mo ṣe oju fun afọju, ati ẹsẹ̀ fun amọkún.

16. Mo ṣe baba fun talaka, ati ọ̀ran ti emi kò mọ̀, mo wadi rẹ̀ ri.

17. Mo si ká ehin ẹ̀rẹkẹ enia buburu, mo si ja ohun ọdẹ na kuro li ehin rẹ̀.

18. Nigbana ni mo wipe, emi o kú ninu itẹ mi, emi o si mu ọjọ mi pọ̀ si i bi iyanrin. (bi ọjọ ti ẹiyẹ Feniksi.)

19. Gbongbo mi ta lọ si ibi omi, ìri si sẹ̀ si ara ẹká mi titi li oru.

20. Ogo mi gberu lọdọ mi, ọrun mi si pada di titun li ọwọ mi.

21. Emi li enia ndẹti silẹ si, nwọn a si duro, nwọn a si dakẹ ninu ìgbimọ mi.

Ka pipe ipin Job 29