Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 27:14-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Bi awọn ọmọ rẹ̀ ba di pupọ̀, fun idà ni, awọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ kì yio yo fun onjẹ.

15. Awọn ti o kù ninu tirẹ̀ li a o sinkú ninu ajakalẹ àrun: awọn opó rẹ̀ kì yio si sọkún.

16. Bi o tilẹ kó fàdaka jọ bi erupẹ, ti o si da aṣọ jọ bi amọ̀.

17. Ki o ma dá a, ṣugbọn awọn olõtọ ni yio lò o; awọn alaiṣẹ̀ ni yio si pin fadaka na.

18. On kọ́ ile rẹ̀ bi kòkoro aṣọ, ati bi agọbukà ti oluṣọ pa.

19. Ọlọrọ̀ yio dubulẹ, ṣugbọn on kì o tùn ṣe bẹ̃ mọ́, o ṣiju rẹ̀, on kò sì si.

20. Ẹ̀ru nla bà a bi omi ṣiṣan, ẹ̀fufu nla ji i gbe lọ li oru.

21. Ẹfufu ila-õrùn gbe e lọ, on si lọ; ati bi iji nla o si fà a kuro ni ipo rẹ̀.

Ka pipe ipin Job 27