Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 27:10-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. On ha le ni inu-didùn si Olodumare, on ha le ma kepe Ọlọrun nigbagbogbo?

11. Emi o kọ́ nyin li ẹkọ́ niti ọwọ Ọlọrun: eyi ti mbẹ lọdọ Olodumare li emi kì yio fi pamọ.

12. Kiyesi i, gbogbo nyin li o ti ri i, nitori kili ẹnyin ṣe jasi asan pọ̀ bẹ̃?

13. Eyi ni ipín enia buburu lọdọ Ọlọrun, ati ogún awọn aninilara, ti nwọn o gbà lọwọ Olodumare.

14. Bi awọn ọmọ rẹ̀ ba di pupọ̀, fun idà ni, awọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ kì yio yo fun onjẹ.

15. Awọn ti o kù ninu tirẹ̀ li a o sinkú ninu ajakalẹ àrun: awọn opó rẹ̀ kì yio si sọkún.

16. Bi o tilẹ kó fàdaka jọ bi erupẹ, ti o si da aṣọ jọ bi amọ̀.

17. Ki o ma dá a, ṣugbọn awọn olõtọ ni yio lò o; awọn alaiṣẹ̀ ni yio si pin fadaka na.

18. On kọ́ ile rẹ̀ bi kòkoro aṣọ, ati bi agọbukà ti oluṣọ pa.

19. Ọlọrọ̀ yio dubulẹ, ṣugbọn on kì o tùn ṣe bẹ̃ mọ́, o ṣiju rẹ̀, on kò sì si.

20. Ẹ̀ru nla bà a bi omi ṣiṣan, ẹ̀fufu nla ji i gbe lọ li oru.

21. Ẹfufu ila-õrùn gbe e lọ, on si lọ; ati bi iji nla o si fà a kuro ni ipo rẹ̀.

22. Nitoripe Olodumare yio kọlù u, kì o sì dasi; on iba yọ̀ lati sá kuro li ọwọ rẹ̀.

Ka pipe ipin Job 27