Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 27:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. PẸLUPẸLU Jobu si tun sọ kún ọ̀rọ owe rẹ̀ o si wipe,

2. Bi Ọlọrun ti mbẹ ẹniti o gba idajọ mi lọ, ati Olodumare ti o bà mi li ọkàn jẹ.

3. Niwọn igba ti ẹmi mi mbẹ ninu mi, ati ti ẹmi Ọlọrun mbẹ ni iho imú mi.

4. Ete mi kì yio sọ̀rọ eké, bẹ̃li ahọn mi kì yio sọ̀rọ ẹ̀tan.

5. Ki a ma ri pe emi ndá nyin li are, titi emi o fi kú emi kì yio ṣi ìwa otitọ mi kuro lọdọ mi.

6. Ododo mi li emi dimú ṣinṣin, emi kì yio si jọwọ rẹ̀ lọwọ; aiya mi kì yio si gan ọjọ kan ninu ọjọ aiye mi.

7. Ki ọta mi ki o dàbi enia buburu, ati ẹniti ndide si mi ki o dàbi ẹni alaiṣododo.

8. Nitoripe kini ireti àgabagebe, nigbati Ọlọrun ba ke ẹmi rẹ̀ kuro, nigbati o si fà a jade.

9. Ọlọrun yio ha gbọ́ adura rẹ̀, nigbati ipọnju ba de si i?

10. On ha le ni inu-didùn si Olodumare, on ha le ma kepe Ọlọrun nigbagbogbo?

11. Emi o kọ́ nyin li ẹkọ́ niti ọwọ Ọlọrun: eyi ti mbẹ lọdọ Olodumare li emi kì yio fi pamọ.

12. Kiyesi i, gbogbo nyin li o ti ri i, nitori kili ẹnyin ṣe jasi asan pọ̀ bẹ̃?

Ka pipe ipin Job 27