9. Okùn ẹgẹ́ ni yio mu u ni gigĩsẹ, awọn igara yio si ṣẹgun rẹ̀.
10. A dẹkùn silẹ fun u lori ilẹ, a si wà ọ̀fin fun u loju ọ̀na.
11. Ẹ̀ru nla yio bà a ni iha gbogbo, yio si le e de ẹsẹ rẹ̀.
12. Ailera rẹ̀ yio di pipa fun ebi, iparun yio dide duro si i ni iha rẹ̀.
13. Yio jẹ ẹ̀ya ara rẹ̀, akọbi ikú ni yio jẹ agbara rẹ̀ run.
14. Eyi ti o ti gbẹkẹle ni a o fàtu kuro ninu agọ rẹ̀, yio si tọ̀ ọba ẹ̀ru nla nì lọ.
15. Yio si ma joko ninu agọ rẹ̀ eyi ti kì iṣe tirẹ̀, imi-õrùn li a ọ fún kakiri si ara ile rẹ̀.
16. Gbongbo rẹ̀ yio gbẹ nisalẹ, a o si ke ẹ̀ka rẹ̀ kuro loke.
17. Iranti rẹ̀ yio parun kuro li aiye, kì yio si orukọ rẹ̀ ni igboro ilu.
18. A o si le e lati inu imọlẹ sinu òkunkun, a o si le e kuro li aiye.
19. Kì yio ni ọmọ bibikunrin tabi ajọbi-kunrin ninu awọn enia rẹ̀, bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o kù ninu agbo ile rẹ̀.
20. Ẹnu yio ya awọn iran ti ìwọ-õrùn si igba ọjọ rẹ̀, gẹgẹ bi ẹ̀ru iwariri ti ba awọn iran ti ila-õrùn.
21. Nitõtọ iru-bẹ̃ ni ibujoko awọn enia buburu, eyi si ni ipo ẹni ti kò mọ̀ Ọlọrun.