Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 18:2-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Nigba wo li ẹnyin o to fi idi ọ̀rọ tì; ẹ rò o, nigbẹhin rẹ̀ li awa o to ma sọ.

3. Nitori kili a ṣe nkà wa si bi ẹranko, ti a si nkà wa si bi ẹni ẹ̀gan li oju nyin!

4. Iwọ nfa ara rẹ ya pẹrẹpẹrẹ ninu ibinu rẹ, ki a ha kọ̀ aiye silẹ nitori rẹ bi? tabi ki a ṣi apata kuro ni ipo rẹ̀?

5. Nitotọ imọlẹ enia buburu li a o pa kuro, ọ̀wọ-iná rẹ̀ kì yio si tan imọlẹ:

6. Imọlẹ yio ṣokunkun ninu agọ rẹ̀, fitila rẹ̀ li a o si pa pẹlu rẹ̀.

7. Irin ẹsẹ agbara rẹ̀ yio di fifọn, ìmọ on tikararẹ ni yio bi i ṣubu.

8. Nipa ẹsẹ on tikararẹ̀ o ti bọ́ sinu àwọn, o si rìn lori okùn didẹ.

9. Okùn ẹgẹ́ ni yio mu u ni gigĩsẹ, awọn igara yio si ṣẹgun rẹ̀.

10. A dẹkùn silẹ fun u lori ilẹ, a si wà ọ̀fin fun u loju ọ̀na.

11. Ẹ̀ru nla yio bà a ni iha gbogbo, yio si le e de ẹsẹ rẹ̀.

12. Ailera rẹ̀ yio di pipa fun ebi, iparun yio dide duro si i ni iha rẹ̀.

13. Yio jẹ ẹ̀ya ara rẹ̀, akọbi ikú ni yio jẹ agbara rẹ̀ run.

14. Eyi ti o ti gbẹkẹle ni a o fàtu kuro ninu agọ rẹ̀, yio si tọ̀ ọba ẹ̀ru nla nì lọ.

Ka pipe ipin Job 18