Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 16:16-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Oju mi ti pọ́n fun ẹkún, ojiji ikú si ṣẹ si ipenpeju mi.

17. Kì iṣe nitori aiṣotitọ kan li ọwọ mi, adura mi si mọ́ pẹlu.

18. A! ilẹ aiye, iwọ máṣe bò ẹ̀jẹ mi, ki ẹkún mi máṣe ni ipò kan.

19. Njẹ nisisiyi kiyesi i! ẹlẹri mi mbẹ li ọrun, ẹri mi si mbẹ loke ọrun.

20. Awọn ọre mi nfi mi ṣẹ̀sin, ṣugbọn oju mi ndà omije sọdọ Ọlọrun.

21. Ibaṣepe ẹnikan le ma ṣe alagbawi fun ẹnikeji lọdọ Ọlọrun, bi enia kan ti iṣe alagbawi fun ẹnikeji rẹ̀.

22. Nitori nigbati iye ọdun diẹ rekọja tan, nigbana ni emi o lọ si ibi ti emi kì yio pada bọ̀.

Ka pipe ipin Job 16