Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 16:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni Jobu dahùn o si wipe,

2. Emi ti gbọ́ iru ohun pipọ bẹ̃ ri; ayọnilẹnu onitunu enia ni gbogbo nyin.

3. Ọ̀rọ asan lè ni opin? tabi kili o gbó ọ laiya ti iwọ fi dahùn.

4. Emi pẹlu le isọ bi ẹnyin, bi ọkàn nyin ba wà ni ipò ọkàn mi, emi le iko ọ̀rọ pọ̀ si nyin li ọrùn, emi a si mì ori mi si nyin.

5. Emi iba fi ọ̀rọ ẹnu mi gbà nyin ni iyanju, ati ṣiṣi ète mi iba si tu ibinujẹ nyin.

6. Bi emi tilẹ sọ̀rọ ibinujẹ mi kò rù; bi mo si tilẹ dakẹ, nibo li itunu mi de?

7. Ṣugbọn nisisiyi, o da mi lagara, iwọ (Ọlọrun) mu gbogbo ẹgbẹ mi takete.

8. Iwọ si fi ikiweje kún mi lara, ti o jẹri tì mi; ati rirù ti o yọ lara mi, o jẹri tì mi li oju.

9. Ibinu rẹ̀ li o fà mi ya, o si ṣọta mi; o pa ehin rẹ̀ keke si mi, ọta mi si gboju rẹ̀ si mi.

10. Nwọn ti fi ẹnu wọn yán si mi, nwọn gbá mi li ẹrẹkẹ ni igbá ẹ̀gan, nwọn kó ara wọn jọ pọ̀ si mi.

11. Ọlọrun ti fi mi le ọwọ ẹni-buburu, o si mu mi ṣubu si ọwọ enia ẹlẹṣẹ.

12. Mo ti joko jẹ, ṣugbọn o fa mi já o si dì mi li ọrùn mu, o si gbọ̀n mi tutu, o si gbe mi kalẹ ṣe àmi itasi rẹ̀.

Ka pipe ipin Job 16