Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 15:30-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. On kì yio jade kuro ninu okunkun, ọ̀wọ-iná ni yio jo ẹká rẹ̀, ati nipasẹ ẹmi ẹnu rẹ̀ ni yio ma kọja lọ kuro.

31. Ki on ki o má ṣe gbẹkẹle asan, o tan ara rẹ̀ jẹ; nitoripe asan ni yio jasi ère rẹ̀.

32. A o mu u ṣẹ ṣaju pipe ọjọ rẹ̀, ẹka rẹ̀ kì yio si tutu.

33. Yio si gbòn talubọ eso rẹ̀ dànu bi àjara, yio si rẹ̀ itana rẹ̀ nù bi ti igi olifi.

34. Nitoripe ajọ awọn àgabagebe yio tuka, iná ni yio si jo agọ abẹtẹlẹ.

35. Nwọn loyun ìwa-ika, nwọn si bi ẹ̀ṣẹ, ikùn wọn si pèse ẹ̀tan.

Ka pipe ipin Job 15