Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 15:3-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. On le ma fi aroye sọ̀rọ ti kò li ère, tabi pẹlu ọ̀rọ ninu eyiti kò le fi ṣe rere?

4. Ani iwọ ṣa ìbẹru tì, iwọ si dí adura lọna niwaju Ọlọrun.

5. Nitoripe ẹnu ara rẹ li o jẹwọ ẹ̀ṣẹ rẹ, iwọ si yàn ahọn alarekereke li ãyò.

6. Ẹnu ara rẹ li o da ọ lẹbi, kì iṣe emi, ani ète ara rẹ li o jẹri tì ọ.

7. Iwọ́ ha iṣe ọkunrin ti a kọ́ bi? tabi a ha dá ọ ṣaju awọn oke?

8. Iwọ gburo aṣiri Ọlọrun ri, tabi iwọ ha dá ọgbọ́n duro sọdọ ara rẹ?

9. Kini iwọ mọ̀ ti awa kò mọ̀, oye kili o ye ọ ti kò si ninu wa.

10. Elewú ogbó ati ògbologbo enia wà pẹlu wa, ti nwọn gbó jù baba rẹ lọ.

11. Itunu Ọlọrun ha kere lọdọ rẹ, ọ̀rọ kan si ṣe jẹjẹ jù lọdọ rẹ.

Ka pipe ipin Job 15