11. Itunu Ọlọrun ha kere lọdọ rẹ, ọ̀rọ kan si ṣe jẹjẹ jù lọdọ rẹ.
12. Ẽṣe ti aiya rẹ fi ndà ọ kiri, tabi kini iwọ tẹjumọ wofin.
13. Ti iwọ fi yi ẹmi rẹ pada lodi si Ọlọrun, ti o fi njẹ ki ọ̀rọkọrọ ki o ma bọ li ẹnu rẹ bẹ̃?
14. Kili enia ti o fi mọ́? ati ẹniti a tinu obinrin bi ti yio fi ṣe olododo?
15. Kiyesi i, on (Ọlọrun) kò gbẹkẹle awọn ẹni-mimọ́ rẹ̀, ani awọn ọrun kò mọ́ li oju rẹ̀.
16. Ambọtori enia, ẹni irira ati elẽri, ti nmu ẹ̀ṣẹ bi ẹni mu omi.
17. Emi o fi hàn ọ, gbọ́ ti emi, eyi ti emi si ri, on li emi o si sọ.
18. Ti awọn ọlọgbọ́n ti pa ni ìtan lati ọdọ awọn baba wọn wá, ti nwọn kò si fi pamọ́.
19. Awọn ti a fi ilẹ aiye fun nikan, alejo kan kò si là wọn kọja.
20. Enia buburu nṣe lãlã, pẹlu irora li ọjọ rẹ̀ gbogbo, ati iye ọdun li a dá silẹ fun aninilara.
21. Iró ìbẹru mbẹ li eti rẹ̀, ninu irora ni alaparun a dide si i.
22. O kò gbagbọ pe on o jade kuro ninu okunkun; a si ṣa a sapakan fun idà.
23. O nwò kakiri fun onjẹ, wipe, nibo li o wà, o mọ̀ pe ọjọ òkunkun sunmọ tosi.
24. Ipọnju pẹlu irora ọkàn yio mu u bẹ̀ru, nwọn o si ṣẹgun rẹ̀ bi ọba ti imura ogun.