Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 13:19-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Tani on ti yio ba mi ṣàroye? njẹ nisisiyi, emi fẹ pa ẹnu mi mọ, emi o si jọwọ ẹmi mi lọwọ.

20. Ṣugbọn ọkan ni, máṣe ṣe ohun meji yi si mi, nigbana ni emi kì yio si fi ara mi pamọ, kuro fun ọ,

21. Fa ọwọ rẹ sẹhin kuro lara mi; má si jẹ ki ẹ̀ru rẹ ki o pá mi laiya.

22. Nigbana ni ki iwọ ki o pè, emi o si dahùn, tabi jẹ ki nma sọ̀rọ, ki iwọ ki o si da mi lohùn.

23. Melo li aiṣedede ati ẹ̀ṣẹ mi, mu mi mọ̀ irekọja ati ẹ̀ṣẹ mi!

24. Nitori kini iwọ ṣe pa oju rẹ mọ́, ti o si yàn mi li ọta rẹ?

25. Iwọ o fa ewe ya ti afẹfẹ nfẹ sihin sọhun: iwọ a si ma lepa akemọlẹ poroporo gbigbẹ!

26. Nitoripe iwọ kọwe ohun kikoro si mi, o si mu mi ni aiṣedede ewe mi.

27. Iwọ kàn àba mọ mi lẹsẹ pẹlu, iwọ si nwò ipa ọ̀na irin mi li awofin, iwọ si nfi ãlà yi gigisẹ mi ka.

28. Ani, yi ẹniti a ti run ka, bi ohun ti o bu, bi aṣọ ti kòkoro jẹ bajẹ.

Ka pipe ipin Job 13