Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 12:4-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Emi dabi ẹniti a nfi ṣe ẹlẹya lọdọ aladugbo rẹ̀, ti o kepe Ọlọrun, ti o si da a lohùn: a nfi olõtọ ẹni-iduro-ṣinṣin rẹrin ẹlẹyà.

5. Ẹgan ni ẹni-òtoṣi, ti ẹsẹ rẹ̀ mura tan lati yọ́ ninu ìro ẹniti ara rọ̀.

6. Agọ awọn igara ngberú, awọn ti o si nmu Ọlọrun binu wà lailewu, awọn ẹniti o si gbá oriṣa mu li ọwọ wọn.

7. Ṣugbọn nisisiyi, bi awọn ẹranko lere, nwọn o kọ́ ọ li ẹkọ́, ati ẹiyẹ oju ọrun, nwọn o si sọ fun ọ.

8. Tabi, ba ilẹ aiye sọ̀rọ, yio si kọ́ ọ, awọn ẹja inu okun yio si sọ fun ọ.

9. Tani kò mọ̀ ninu gbogbo wọnyi pe, ọwọ Oluwa li o ṣe nkan yi?

10. Lọwọ ẹniti ẹmi ohun alãye gbogbo gbé wà, ati ẹmi gbogbo araiye.

11. Eti ki idán ọ̀rọ wò bi? tabi adùn ẹnu ki isi tọ onjẹ rẹ̀ wò?

12. Awọn arugbo li ọgbọ́n wà fun, ati ninu gigùn ọjọ li oye.

13. Pẹlu rẹ̀ (Ọlọrun) li ọgbọ́n ati agbarà, on ni ìmọ ati oye,

14. Kiyesi i, o biwó, a kò si le igbe ró mọ́, o se enia mọ́, kò si sí iṣisilẹ̀ kan.

15. Kiyesi i, o da awọn omi duro, nwọn si gbẹ, o si rán wọn jade, nwọn si ṣẹ bo ilẹ aiye yipo.

16. Pẹlu rẹ̀ li agbara ati ọgbọ́n, ẹniti nṣìna ati ẹniti imu ni ṣìna tirẹ̀ ni nwọn iṣe.

17. O mu awọn igbimọ̀ lọ nihoho, a si sọ awọn onidajọ di wère.

18. O tu ide ọba, o si fi àmure gbà wọn li ọ̀ja.

19. O mu awọn alufa lọ nihoho, o si tẹ ori awọn alagbara bá.

20. O mu ọ̀rọ-ẹnu ẹni-igbẹkẹle kuro, o si ra awọn àgbàgbà ni iye.

Ka pipe ipin Job 12