Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Job 12:18-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. O tu ide ọba, o si fi àmure gbà wọn li ọ̀ja.

19. O mu awọn alufa lọ nihoho, o si tẹ ori awọn alagbara bá.

20. O mu ọ̀rọ-ẹnu ẹni-igbẹkẹle kuro, o si ra awọn àgbàgbà ni iye.

21. O bù ẹ̀gan lu awọn ọmọ-alade, o si tú àmure awọn alagbara.

22. O hudi ohun ti o sigbẹ jade lati inu òkunkun wá, o si mu ojiji ikú jade wá sinu imọlẹ̀.

23. On a mu orilẹ-ède bi si i, a si run wọn, on a sọ orilẹ-ède di nla, a si tun ṣẹ́ wọn kù.

24. On a gbà aiya olú awọn enia aiye, a si ma mu wọn wọ́ kakiri ninu iju nibiti ọ̀na kò si.

25. Nwọn a ma fi ọwọ ta ilẹ ninu òkunkun laisi imọlẹ, on a si ma mu wọn tàse irin bi ọmuti.

Ka pipe ipin Job 12