Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 18:6-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Ẹnyin o si ṣe apejuwe ilẹ na li ọ̀na meje, ẹnyin o si mú apejuwe tọ̀ mi wá nihin, ki emi ki o le ṣẹ́ keké rẹ̀ fun nyin nihin niwaju OLUWA Ọlọrun wa.

7. Nitoriti awọn ọmọ Lefi kò ní ipín lãrin nyin; nitori iṣẹ-alufa OLUWA ni iní wọn: ati Gadi, ati Reubeni, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, ti gbà ilẹ-iní wọn na ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun wọn.

8. Awọn ọkunrin na si dide, nwọn si lọ: Joṣua si paṣẹ fun awọn ti o lọ ṣe apejuwe ilẹ na, wipe, Ẹ lọ, ki ẹ si rìn ilẹ na já, ki ẹ si ṣe apejuwe rẹ̀, ki ẹ si pada tọ̀ mi wá, ki emi ki o le ṣẹ́ keké fun nyin niwaju OLUWA ni Ṣilo.

9. Awọn ọkunrin na si lọ, nwọn si là ilẹ na já, nwọn si ṣe apejuwe rẹ̀ sinu iwé ni ilu ilu li ọ̀na meje, nwọn si pada tọ̀ Joṣua wá, si ibudó ni Ṣilo.

10. Joṣua si ṣẹ́ keké fun wọn ni Ṣilo niwaju OLUWA: nibẹ̀ ni Joṣua si pín ilẹ na fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ipín wọn.

11. Ilẹ ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini yọ jade, gẹgẹ bi idile wọn: àla ipín wọn si yọ si agbedemeji awọn ọmọ Juda ati awọn ọmọ Josefu.

12. Àla wọn ni ìha ariwa si ti Jordani lọ; àla na si gòke lọ si ìha Jeriko ni ìha ariwa, o si là ilẹ òke lọ ni iwọ-õrùn; o si yọ si aginjù Beti-afeni.

13. Àla na si ti ibẹ̀ lọ si Lusi, si ìha Lusi (ti ṣe Beti-eli), ni ìha gusù; àla na si sọkale lọ si Atarotu-adari, lẹba òke ti mbẹ ni gusù Beti-horoni isalẹ.

14. A si fà àla na lọ, o si yi si ìha ìwọ-õrùn lọ si gusù, lati òke ti mbẹ niwaju Beti-horoni ni ìha gusù; o si yọ si Kiriati-baali (ti ṣe Kiriati-jearimu), ilu awọn ọmọ Juda kan: eyi ni apa ìwọ-õrùn.

15. Ati apa gusù ni lati ipẹkun Kiriati-jearimu, àla na si yọ ìwọ-õrùn, o si yọ si isun omi Neftoa:

16. Àla na si sọkalẹ lọ si ipẹkun òke ti mbẹ niwaju afonifoji ọmọ Hinnomu, ti o si mbẹ ni afonifoji Refaimu ni ìha ariwa; o si sọkalẹ lọ si afonifoji Hinnomu, si apa Jebusi ni ìha gusù, o si sọkalẹ lọ si Eni-rogeli;

17. A si fà a lati ariwa lọ, o si yọ si Eni-ṣemeṣi, o si yọ si Gelilotu, ti o kọjusi òke Adummimu; o si sọkalẹ lọ si okuta Bohani ọmọ Reubeni;

18. O si kọja lọ si apa ibi ti o kọjusi Araba ni ìha ariwa, o si sọkalẹ lọ si Araba:

19. Àla na si kọja lọ dé apa Beti-hogla ni ìha ariwa: àla na si yọ ni ìha ariwa si kọ̀rọ Okun Iyọ̀, ni ipẹkun gusù ti Jordani: eyi ni àla gusù.

20. Jordani si ni àla rẹ̀ ni ìha ìla-õrùn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Benjamini, li àgbegbe rẹ̀ kakiri, gẹgẹ bi idile wọn.

Ka pipe ipin Joṣ 18