Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 17:7-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Àla Manasse si lọ lati Aṣeri dé Mikmeta, ti mbẹ niwaju Ṣekemu; àla na si lọ titi ni ìha ọtún, sọdọ awọn ara Eni-tappua.

8. Manasse li o ní ilẹ Tappua: ṣugbọn Tappua li àla Manasse jẹ́ ti awọn ọmọ Efraimu.

9. Àla rẹ̀ si sọkalẹ lọ si odò Kana, ni ìha gusù odò na: ilu Efraimu wọnyi wà lãrin awọn ilu Manasse: àla Manasse pẹlu si wà ni ìha ariwa odò na, o si yọ si okun:

10. Ni ìha gusù ti Efraimu ni, ati ni ìha ariwa ti Manasse ni, okun si ni àla rẹ̀; nwọn si dé Aṣeri ni ìha ariwa, ati Issakari ni ìha ìla-õrùn.

11. Manasse si ní ni Issakari ati ni Aṣeri, Beti-ṣeani ati awọn ilu rẹ̀, ati Ibleamu ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Dori ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Enidori ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Taanaki ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Megiddo ati awọn ilu rẹ̀, ani òke mẹta na.

Ka pipe ipin Joṣ 17