50. Ati Anabu, ati Eṣtemo, ati Animu;
51. Ati Goṣeni, ati Holoni, ati Gilo; ilu mọkanla pẹlu ileto wọn.
52. Arabu, ati Duma, ati Eṣani;
53. Ati Janimu, ati Beti-tappua, ati Afeka;
54. Ati Humta, ati Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni), ati Siori; ilu meṣan pẹlu ileto wọn.
55. Maoni, Karmeli, ati Sifu, ati Juta;
56. Ati Jesreeli, ati Jokdeamu, ati Sanoa;
57. Kaini, Gibea, ati Timna; ilu mẹwa pẹlu ileto wọn.
58. Halhulu, Beti-suru, ati Gedori;
59. Ati Maarati, ati Beti-anotu, ati Eltekoni; ilu mẹfa pẹlu ileto wọn.
60. Kiriati-baali (ti iṣe Kiriati-jearimu), ati Rabba; ilu meji pẹlu ileto wọn.
61. Li aginjù, Beti-araba, Middini, ati Sekaka;
62. Ati Nibṣani, ati Ilu Iyọ̀, ati Eni-gedi; ilu mẹfa pẹlu ileto wọn.
63. Bi o si ṣe ti awọn Jebusi nì, awọn ara Jerusalemu, awọn ọmọ Juda kò le lé wọn jade: ṣugbọn awọn Jebusi mbá awọn ọmọ Juda gbé ni Jerusalemu, titi di oni-oloni.