20. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn.
21. Ilu ipẹkun ẹ̀ya awọn ọmọ Juda li àgbegbe Edomu ni Gusù ni Kabseeli, ati Ederi, ati Jaguri;
22. Ati Kina, ati Dimona, ati Adada;
23. Ati Kedeṣi, ati Hasori, ati Itnani;
24. Sifu, ati Telemu, ati Bealotu;
25. Ati Haṣori-hadatta, ati Keriotu-hesroni (ti iṣe Hasori);
26. Amamu, ati Ṣema, ati Molada;
27. Ati Hasari-gada, ati Heṣmoni, ati Beti-peleti;
28. Ati Hasari-ṣuali, ati Beeri-ṣeba, ati Bisi-otia;
29. Baala, ati Iimu, ati Esemu;
30. Ati Eltoladi, ati Kesili, ati Horma;
31. Ati Siklagi, ati Madmanna, ati Sansanna;