Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 15:17-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Otnieli ọmọ Kenasi, arakunrin Kalebu, si kó o: o si fi Aksa ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya.

18. O si ṣe, bi Aksa ti dé ọdọ rẹ̀, o mu u bère ọ̀rọ kan lọwọ baba rẹ̀: Aksa si sọkalẹ lori kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; Kalebu si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ́?

19. On si dahùn pe, Ta mi li ọrẹ kan; nitoriti iwọ ti fun mi ni ilẹ Gusù, fun mi ni isun omi pẹlu. O si fi isun òke ati isun isalẹ fun u.

20. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn.

21. Ilu ipẹkun ẹ̀ya awọn ọmọ Juda li àgbegbe Edomu ni Gusù ni Kabseeli, ati Ederi, ati Jaguri;

22. Ati Kina, ati Dimona, ati Adada;

Ka pipe ipin Joṣ 15