orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣ 12 Yorùbá Bibeli (YCE)

Àwọn Ọba Tí Mose Ṣẹgun

1. NJẸ wọnyi ni awọn ọba ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli pa, ti nwọn si gbà ilẹ wọn li apa keji Jordani, ni ìha ìla-õrùn, lati odò Arnoni lọ titi dé òke Hermoni, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ni ìha ìla-õrun:

2. Sihoni ọba Amori, ti ngbé Heṣboni, ti o si jọba lati Aroeri, ti mbẹ leti odò Arnoni, ati ilu ti o wà lãrin afonifoji na, ati àbọ Gileadi, ani titi dé odò Jaboku, àgbegbe awọn ọmọ Ammoni;

3. Ati ni pẹtẹlẹ̀ lọ dé okun Kinnerotu ni ìha ìla-õrùn, ati titi dé okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀ ni ìha ìla-õrun, li ọ̀na Beti-jeṣimotu; ati lati gusù lọ nisalẹ ẹsẹ̀-òke Pisga:

4. Ati àgbegbe Ogu ọba Baṣani, ọkan ninu awọn ti o kù ninu awọn Refaimu, èniti ngbé Aṣtarotu ati Edrei,

5. O si jọba li òke Hermoni, ati ni Saleka, ati ni gbogbo Baṣani, titi o fi dé àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati àbọ Gileadi, àla Sihoni ọba Heṣboni.

6. Mose iranṣẹ OLUWA ati awọn ọmọ Israeli kọlù wọn: Mose iranṣẹ OLUWA si fi i fun awọn ọmọ Reubeni ni ilẹ-iní, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse.

Àwọn Ọba Tí Joṣua Ṣẹgun

7. Wọnyi li awọn ọba ilẹ na, ti Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa li apa ihin Jordani, ni ìwọ-õrùn, lati Baali-gadi li afonifoji Lebanoni ani titidé òke Halaki, li ọ̀na òke Seiri; ti Joṣua fi fun awọn ẹ̀ya Israeli ni ilẹ-iní gẹgẹ bi ipín wọn.

8. Ni ilẹ òke, ati ni ilẹ titẹju, ati ni pẹtẹlẹ̀, ati li ẹsẹ̀-òke, ati li aginjù, ati ni Gusù; awọn Hitti, awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi:

9. Ọba Jeriko, ọkan; ọba Ai, ti o wà lẹba Beti-eli, ọkan.

10. Ọba Jerusalemu, ọkan; ọba Hebroni, ọkan;

11. Ọba Jarmutu, ọkan; ọba Lakiṣi, ọkan;

12. Ọba Egloni, ọkan; ọba Geseri, ọkan;

13. Ọba Debiri, ọkan; ọba Gederi, ọkan;

14. Ọba Horma, ọkan; ọba Aradi, ọkan;

15. Ọba Libna, ọkan; ọba Adullamu, ọkan;

16. Ọba Makkeda, ọkan; ọba Betieli, ọkan;

17. Ọba Tappua, ọkan; ọba Heferi, ọkan;

18. Ọba Afeki, ọkan; ọba Laṣaroni, ọkan;

19. Ọba Madoni, ọkan; ọba Hasoru, ọkan;

20. Ọba Ṣimroni-meroni, ọkan; ọba Akṣafu, ọkan;

21. Ọba Taanaki, ọkan; ọba Megiddo, ọkan;

22. Ọba Kedeṣi, ọkan; ọba Jokneamu ti Karmeli, ọkan;

23. Ọba Doru, li òke Doru, ọkan; ọba awọn orilẹ-ède Gilgali, ọkan;

24. Ọba Tirsa, ọkan; gbogbo awọn ọba na jẹ́ mọkanlelọgbọ̀n.