Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 8:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI akoko na, li Oluwa wi, ni nwọn o hú egungun awọn ọba Juda ati egungun awọn ijoye, egungun awọn alufa ati egungun awọn woli, ati egungun awọn olugbe Jerusalemu kuro ninu isà wọn:

2. Nwọn o si tẹ́ wọn siwaju õrùn ati òṣupa ati gbogbo ogun ọrun, ti nwọn ti fẹ, ti nwọn si ti sìn, awọn ti nwọn si rìn tọ̀ lẹhin, ti nwọn si wá, ti nwọn si foribalẹ fun: a kì yio kó wọn jọ, bẹ̃li a kì yio sin wọn, nwọn o di àtan li oju ilẹ-aiye.

3. Awon iyokù ti o kù ninu idile buburu yi yio yan kikú jù yiyè lọ: ni ibi gbogbo ti nwọn kù si, ti emi ti tì wọn jade si, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

4. Iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi; enia le ṣubu li aidide mọ? tabi enia le pada, ki o má tun yipada mọ?

Ka pipe ipin Jer 8