Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 51:30-48 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. Awọn akọni Babeli ti dẹkun jijà, nwọn ti joko ninu ile-odi wọn; agbara wọn ti tán; nwọn di obinrin, nwọn tinabọ ibugbe rẹ̀; a ṣẹ́ ikere rẹ̀.

31. Ẹnikan ti nsare yio sare lọ lati pade ẹnikeji ti nsare, ati onṣẹ kan lati pade onṣẹ miran, lati jiṣẹ fun ọba Babeli pe: a kó ilu rẹ̀ ni iha gbogbo.

32. Ati pe, a gbà awọn asọda wọnni, nwọn si ti fi ifefe joná, ẹ̀ru si ba awọn ọkunrin ogun.

33. Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Ọmọbinrin Babeli dabi ilẹ ipaka, li akoko ti a o pa ọka lori rẹ̀: sibẹ ni igba diẹ si i, akoko ikore rẹ̀ mbọ fun u.

34. Nebukadnessari, ọba Babeli, ti jẹ mi run, o ti tẹ̀ mi mọlẹ, o ti ṣe mi ni ohun-elo ofo, o ti gbe mi mì gẹgẹ bi ọ̀wawa, o ti fi ohun didara mi kún ikun rẹ̀, o ti le mi jade.

35. Ki ìwa-ika ti a hù si mi ati ẹran-ara mi ki o wá sori Babeli, bẹ̃ni iwọ olugbe Sioni yio wi; ati ẹ̀jẹ mi lori awọn olugbe, ara Kaldea, bẹ̃ni iwọ, Jerusalemu, yio wi.

36. Nitorina bayi ni Oluwa wi; Wò o, emi o gba ijà rẹ jà, emi o si gba ẹsan rẹ, emi o si gbẹ okun rẹ̀, emi o si mu gbogbo orisun rẹ̀ gbẹ.

37. Babeli yio si di òkiti àlapa, ibugbe ọ̀wawa, iyanu, ẹsin, laini olugbe.

38. Nwọn o jumọ bú bi kiniun: nwọn o si ke bi ọmọ kiniun.

39. Ninu oru wọn li emi o ṣe ase ohun mimu fun wọn, emi o si mu wọn yo bi ọ̀muti, ki nwọn ki o le ma yọ̀, ki nwọn ki o si sun orun lailai, ki nwọn ki o má si jí mọ́, li Oluwa wi.

40. Emi o si mu wọn wá bi ọdọ-agutan si ibi pipa, bi àgbo pẹlu obukọ.

41. Bawo li a kó Ṣeṣaki! bawo li ọwọ wọn ṣe tẹ iyìn gbogbo ilẹ aiye! bawo ni Babeli ṣe di iyanu lãrin awọn orilẹ-ède!

42. Okun wá sori Babeli: a si fi ọ̀pọlọpọ riru omi rẹ̀ bò o mọlẹ.

43. Ilu rẹ̀ ni ahoro, ilẹ gbigbe, ati aginju: ilẹ ninu eyiti ẹnikẹni kò gbe, bẹ̃ni ọmọ enia kò kọja nibẹ.

44. Nitori emi o jẹ Beli niya ni Babeli, emi o si mu eyiti o ti gbemì jade li ẹnu rẹ̀: awọn orilẹ-ède kì yio jumọ ṣàn lọ pọ si ọdọ rẹ̀ mọ: lõtọ odi Babeli yio wó.

45. Enia mi, ẹ jade ni ãrin rẹ̀, ki olukuluku nyin si gba ẹmi rẹ̀ là kuro ninu ibinu gbigbona Oluwa!

46. Ati ki ọkàn nyin má ba rẹ̀wẹsi, ati ki ẹ má ba bẹ̀ru, nitori iró ti a o gbọ́ ni ilẹ na; nitori iró na yio de li ọdun na, ati lẹhin na iró yio de li ọdun keji, ati ìwa-ika ni ilẹ na, alakoso yio dide si alakoso.

47. Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, ti emi o bẹ awọn ere fifin Babeli wò: oju yio si tì gbogbo ilẹ rẹ̀, gbogbo awọn olupa rẹ̀ yio si ṣubu li ãrin rẹ̀.

48. Ọrun ati aiye, ati gbogbo ohun ti o wà ninu wọn, yio si kọrin lori Babeli: nitori awọn afiniṣeijẹ yio wá sori rẹ̀ lati ariwa, li Oluwa wi.

Ka pipe ipin Jer 51