Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 51:3-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Jẹ ki tafatafa fà ọrun rẹ̀ si ẹniti nfà ọrun, ati si ẹniti o nṣogo ninu ẹ̀wu irin rẹ̀: ẹ má si ṣe dá awọn ọdọmọdekunrin rẹ̀ si, ẹ run gbogbo ogun rẹ̀ patapata.

4. Awọn ti a pa yio si ṣubu ni ilẹ awọn ara Kaldea, awọn ti a gun li ọ̀kọ, yio si ṣubu ni ita rẹ̀.

5. Nitori Israeli ati Juda, kì iṣe opó niwaju Ọlọrun wọn, niwaju Oluwa, awọn ọmọ-ogun; nitori ilẹ wọn (Babeli) ti kún fun ẹbi si Ẹni-Mimọ Israeli.

6. Ẹ salọ kuro lãrin Babeli, ki olukuluku enia ki o si gbà ọkàn rẹ̀ là: ki a máṣe ke nyin kuro ninu aiṣedede rẹ̀; nitori eyi li àkoko igbẹsan fun Oluwa; yio san ère iṣẹ fun u.

7. Babeli jẹ ago wura lọwọ Oluwa, ti o mu gbogbo ilẹ aiye yo bi ọ̀muti: awọn orilẹ-ède ti mu ninu ọti-waini rẹ̀; nitorina ni awọn orilẹ-ède nṣogo.

8. Babeli ṣubu, a si fọ ọ lojiji: ẹ hu fun u; ẹ mu ikunra fun irora rẹ̀, bi o jẹ bẹ̃ pe, yio san fun u.

9. Awa fẹ wò Babeli sàn, ṣugbọn kò sàn; ẹ kọ̀ ọ silẹ, ki ẹ si jẹ ki a lọ, olukuluku si ilẹ rẹ̀: nitori ẹbi rẹ̀ de ọrun, a si gbe e soke de awọsanma.

10. Oluwa mu ododo wa jade; ẹ wá, ẹ jẹ ki a si kede iṣẹ Oluwa Ọlọrun wa ni Sioni.

11. Pọ́n ọfa mu: mu asà li ọwọ: Oluwa ti ru ẹmi awọn ọba Media soke: nitori ipinnu rẹ̀ si Babeli ni lati pa a run, nitoripe igbẹsan Oluwa ni, igbẹsan fun tempili rẹ̀.

12. Gbé asia soke lori odi Babeli, mu awọn iṣọ lagbara, mu awọn oluṣọ duro, ẹ yàn ẹ̀bu: nitori Oluwa gbero, o si ṣe eyi ti o wi si awọn olugbe Babeli.

13. Iwọ ẹniti ngbe ẹba omi pupọ, ti o pọ ni iṣura, opin rẹ de, iwọn ikogun-ole rẹ kún.

14. Oluwa awọn ọmọ-ogun ti fi ẹmi rẹ̀ bura pe, ni kikún emi o fi enia kún ọ gẹgẹ bi ẹlẹnga; nwọn o si pa ariwo ogun lori rẹ.

15. On ti da aiye nipa agbara rẹ̀, on ti ṣe ipinnu araiye nipa ọgbọ́n rẹ̀, o si tẹ́ awọn ọrun nipa oye rẹ̀.

16. Nigbati o ba san ãrá, ọ̀pọlọpọ omi ni mbẹ li oju ọrun; o si mu kũku goke lati opin aiye wá, o dá manamana fun òjo, o si mu ẹfũfu jade lati inu iṣura rẹ̀ wá.

Ka pipe ipin Jer 51