Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 51:16-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Nigbati o ba san ãrá, ọ̀pọlọpọ omi ni mbẹ li oju ọrun; o si mu kũku goke lati opin aiye wá, o dá manamana fun òjo, o si mu ẹfũfu jade lati inu iṣura rẹ̀ wá.

17. Aṣiwere ni gbogbo enia, nitori oye kò si; oju tì gbogbo alagbẹdẹ nitori ere, nitori ere didà rẹ̀ eke ni, kò si sí ẹmi ninu wọn.

18. Asan ni nwọn, ati iṣẹ iṣina: ni ìgba ibẹ̀wo wọn, nwọn o ṣegbe.

19. Ipin Jakobu kò dabi wọn: nitori on ni iṣe Ẹlẹda ohun gbogbo: Israeli si ni ẹ̀ya ijogun rẹ̀: Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.

20. Iwọ ni òlù mi, ohun elo-ogun: emi o fi ọ fọ awọn orilẹ-ède tũtu, emi o si fi ọ pa awọn ijọba run;

21. Emi o si fi ọ fọ ẹṣin ati ẹlẹṣin tũtu; emi o si fi ọ fọ kẹ̀kẹ ati ẹniti o gùn u tũtu;

22. Emi o si fi ọ fọ ọkunrin ati obinrin tũtu; emi o si fi ọ fọ arugbo ati ọmọde tũtu; emi o si fi ọ fọ ọdọmọkunrin ati wundia tũtu;

23. Emi o si fi ọ fọ oluṣọ-agutan ati agbo-ẹran rẹ̀ tũtu, emi o si fi ọ fọ àgbẹ ati àjaga-malu rẹ̀ tũtu; emi o si fi ọ fọ awọn balẹ ati awọn ijoye tũtu.

24. Ṣugbọn emi o si san fun Babeli ati fun gbogbo awọn olugbe Kaldea gbogbo ibi wọn, ti nwọn ti ṣe ni Sioni li oju nyin, li Oluwa wi.

25. Wo o, emi dojukọ ọ, iwọ oke ipanirun! li Oluwa wi, ti o pa gbogbo ilẹ aiye run; emi o si nà ọwọ mi sori rẹ, emi o si yi ọ lulẹ lati ori apata wá, emi o si ṣe ọ ni oke jijona.

26. Ki nwọn ki o má le mu okuta igun ile, tabi okuta ipilẹ ninu rẹ, ṣugbọn iwọ o di ahoro lailai, li Oluwa wi.

Ka pipe ipin Jer 51