Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 51:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BAYI li Oluwa wi: wò o, emi o rú afẹfẹ iparun soke si Babeli, ati si awọn ti ngbe ãrin awọn ti o dide si mi;

2. Emi o si rán awọn alatẹ si Babeli, ti yio fẹ ẹ, nwọn o si sọ ilẹ rẹ̀ di ofo: nitori li ọjọ wahala ni nwọn o wà lọdọ rẹ̀ yikakiri.

3. Jẹ ki tafatafa fà ọrun rẹ̀ si ẹniti nfà ọrun, ati si ẹniti o nṣogo ninu ẹ̀wu irin rẹ̀: ẹ má si ṣe dá awọn ọdọmọdekunrin rẹ̀ si, ẹ run gbogbo ogun rẹ̀ patapata.

4. Awọn ti a pa yio si ṣubu ni ilẹ awọn ara Kaldea, awọn ti a gun li ọ̀kọ, yio si ṣubu ni ita rẹ̀.

5. Nitori Israeli ati Juda, kì iṣe opó niwaju Ọlọrun wọn, niwaju Oluwa, awọn ọmọ-ogun; nitori ilẹ wọn (Babeli) ti kún fun ẹbi si Ẹni-Mimọ Israeli.

6. Ẹ salọ kuro lãrin Babeli, ki olukuluku enia ki o si gbà ọkàn rẹ̀ là: ki a máṣe ke nyin kuro ninu aiṣedede rẹ̀; nitori eyi li àkoko igbẹsan fun Oluwa; yio san ère iṣẹ fun u.

7. Babeli jẹ ago wura lọwọ Oluwa, ti o mu gbogbo ilẹ aiye yo bi ọ̀muti: awọn orilẹ-ède ti mu ninu ọti-waini rẹ̀; nitorina ni awọn orilẹ-ède nṣogo.

8. Babeli ṣubu, a si fọ ọ lojiji: ẹ hu fun u; ẹ mu ikunra fun irora rẹ̀, bi o jẹ bẹ̃ pe, yio san fun u.

9. Awa fẹ wò Babeli sàn, ṣugbọn kò sàn; ẹ kọ̀ ọ silẹ, ki ẹ si jẹ ki a lọ, olukuluku si ilẹ rẹ̀: nitori ẹbi rẹ̀ de ọrun, a si gbe e soke de awọsanma.

10. Oluwa mu ododo wa jade; ẹ wá, ẹ jẹ ki a si kede iṣẹ Oluwa Ọlọrun wa ni Sioni.

11. Pọ́n ọfa mu: mu asà li ọwọ: Oluwa ti ru ẹmi awọn ọba Media soke: nitori ipinnu rẹ̀ si Babeli ni lati pa a run, nitoripe igbẹsan Oluwa ni, igbẹsan fun tempili rẹ̀.

Ka pipe ipin Jer 51