Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 5:6-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nitorina kiniun lati inu igbo wa yio pa wọn, ikõko aṣálẹ̀ yio pa wọn run, ẹkùn yio mã ṣọ ilu wọn: ẹnikẹni ti o ba ti ibẹ jade li a o ya pẹrẹpẹrẹ: nitori ẹ̀ṣẹ wọn pọ̀, ati ipẹhinda wọn le.

7. Emi o ha ṣe dari eyi ji ọ? awọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si fi eyi ti kì iṣe ọlọrun bura: emi ti mu wọn bura, ṣugbọn nwọn ṣe panṣaga, nwọn si kó ara wọn jọ si ile àgbere.

8. Nwọn jẹ akọ ẹṣin ti a bọ́ rere ti nrin kiri, olukuluku nwọn nyán si aya aladugbo rẹ̀.

9. Emi kì yio ha ṣe ibẹwo nitori nkan wọnyi? li Oluwa wi, ẹmi mi kì yio ha gbẹsan lara iru orilẹ-ède bi eyi?

10. Ẹ goke lọ si ori odi rẹ̀, ki ẹ si parun; ṣugbọn ẹ máṣe pa a run tan: ẹ wó kùrùkúrù rẹ̀ kuro nitori nwọn kì iṣe ti Oluwa.

11. Nitori ile Israeli ati ile Juda ti huwa arekereke gidigidi si mi, li Oluwa wi.

12. Nwọn sẹ Oluwa, wipe, Kì iṣe on, ibi kò ni wá si ori wa, awa kì yio si ri idà tabi ìyan:

13. Awọn woli yio di ẹfufu, ọ̀rọ kò sì si ninu wọn: bayi li a o ṣe si wọn.

14. Nitorina bayi li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi, nitori ẹnyin sọ ọ̀rọ yi, sa wò o, emi o sọ ọ̀rọ mi li ẹnu rẹ di iná, ati awọn enia yi di igi, yio si jo wọn run.

15. Wò o emi o mu orilẹ-ède kan wá sori nyin lati ọ̀na jijin, ẹnyin ile Israeli, li Oluwa wi, orilẹ-ède alagbara ni, orilẹ-ède lati igbãni wá ni, orilẹ-ède ti iwọ kò mọ̀ ede rẹ̀, bẹ̃ni iwọ kò gbọ́ eyiti o nwi.

16. Apó ọfa rẹ̀ dabi isa-okú ti a ṣi, akọni enia ni gbogbo wọn.

Ka pipe ipin Jer 5