Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 5:15-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Wò o emi o mu orilẹ-ède kan wá sori nyin lati ọ̀na jijin, ẹnyin ile Israeli, li Oluwa wi, orilẹ-ède alagbara ni, orilẹ-ède lati igbãni wá ni, orilẹ-ède ti iwọ kò mọ̀ ede rẹ̀, bẹ̃ni iwọ kò gbọ́ eyiti o nwi.

16. Apó ọfa rẹ̀ dabi isa-okú ti a ṣi, akọni enia ni gbogbo wọn.

17. On o si jẹ ikore rẹ ati onjẹ rẹ, nwọn o jẹ awọn ọmọkunrin ati awọn ọmọbinrin rẹ, nwọn o si jẹ agbo rẹ ati ọwọ́-ẹran rẹ, nwọn o jẹ àjara rẹ ati igi ọ̀pọtọ rẹ, nwọn o fi idà sọ ilu olodi rẹ ti iwọ gbẹkẹle di ahoro.

18. Ṣugbọn li ọjọ wọnnì, li Oluwa wi, emi kì yio ṣe iparun nyin patapata.

19. Yio si ṣe, nigbati ẹnyin o wipe: Ẽṣe ti Oluwa Ọlọrun wa fi ṣe gbogbo ohun wọnyi si wa? nigbana ni iwọ o da wọn lohùn: Gẹgẹ bi ẹnyin ti kọ̀ mi, ti ẹnyin si nsìn ọlọrun ajeji ni ilẹ nyin, bẹ̃ni ẹnyin o sin alejo ni ilẹ ti kì iṣe ti nyin.

20. Kede eyi ni ile Jakobu, pokiki rẹ̀ ni Juda wipe,

21. Ẹ gbọ́ eyi nisisiyi, ẹnyin aṣiwere enia ati alailọgbọ́n; ti o ni oju, ti kò si riran, ti o ni eti ti kò si gbọ́.

22. Ẹ kò ha bẹ̀ru mi; li Oluwa wi, ẹ kì yio warìri niwaju mi, ẹniti o fi yanrin ṣe ipãla okun, opin lailai ti kò le rekọja: ìgbì rẹ̀ kọlu u, kò si le bori rẹ̀, o pariwo, ṣugbọn kò lè re e kọja?

23. Ṣugbọn enia yi ni aiya isàgun ati iṣọtẹ si, nwọn sọ̀tẹ, nwọn si lọ.

24. Bẹ̃ni nwọn kò wi li ọkàn wọn pe, Ẹ jẹ ki a bẹ̀ru Oluwa Ọlọrun wa wayi, ẹniti o fun wa ni òjo akọrọ ati arọkuro ni igba rẹ̀: ti o fi ọ̀sẹ ikore ti a pinnu pamọ fun wa.

25. Aiṣedede nyin ti yi gbogbo ohun wọnyi pada, ati ẹ̀ṣẹ nyin ti fà ohun rere sẹhin kuro lọdọ nyin.

26. Nitori lãrin enia mi ni a ri enia ìka, nwọn wò kakiri, bi biba ẹniti ndẹ ẹiyẹ, nwọn dẹ okùn nwọn mu enia.

27. Bi àgo ti o kún fun ẹiyẹ, bẹ̃ni ile wọn kún fun ẹ̀tan, nitorina ni nwọn ṣe di nla, nwọn si di ọlọrọ̀.

28. Nwọn sanra, nwọn ndán, pẹlupẹlu nwọn rekọja ni ìwa-buburu, nwọn kò ṣe idajọ, nwọn kò dajọ ọ̀ran alainibaba, ki nwọn le ri rere; nwọn kò si dajọ are awọn talaka.

29. Emi kì yio ha ṣe ibẹwò nitori nkan wọnyi, li Oluwa wi, ẹmi mi kì yio ha gbẹsan lori orilẹ-ède bi eyi?

30. Ohun iyanu ati irira li a ṣe ni ilẹ na.

31. Awọn woli sọ asọtẹlẹ eke, ati awọn alufa ṣe akoso labẹ ọwọ wọn, awọn enia mi si fẹ ki o ri bẹ̃; kini ẹnyin o si ṣe ni igbẹhin rẹ̀?

Ka pipe ipin Jer 5