Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 46:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Jeremiah, woli wá si awọn orilẹ-ède.

2. Si Egipti, si ogun Farao-Neko, ọba Egipti, ti o wà lẹba odò Ferate ni iha Karkemiṣi, ti Nebukadnessari, ọba Babeli, kọlu ni ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda.

3. Ẹ mura apata ati asà, ẹ si sunmọ tosi si oju ìja,

4. Ẹ di ẹṣin ni gãrì; ẹ gùn wọn, ẹnyin ẹlẹṣin, ẹ duro lẹsẹsẹ ninu akoro nyin; ẹ dan ọ̀kọ, ẹ wọ ẹwu irin.

5. Ẽṣe ti emi ti ri wọn ni ibẹ̀ru ati ni ipẹhinda? awọn alagbara wọn li a lù bolẹ, nwọn sa, nwọn kò si wò ẹhin: ẹ̀ru yika kiri, li Oluwa wi.

6. Ẹni ti o yara, kì yio salọ, alagbara ọkunrin kì yio si sala: ni iha ariwa lẹba odò Ferate ni nwọn o kọsẹ̀, nwọn o si ṣubu.

Ka pipe ipin Jer 46