Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 43:7-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nwọn si wá si ilẹ Egipti: nitori nwọn kò gbà ohùn Oluwa gbọ́: bayi ni nwọn wá si Tafanesi.

8. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá ni Tafanesi, wipe,

9. Mu okuta nla li ọwọ rẹ ki o si fi wọn pamọ sinu amọ̀, ni ile-iná briki ti o wà ni ẹnu-ọ̀na ile Farao ni Tafanesi, li oju awọn ọkunrin Juda.

10. Ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi, pe, wò o, emi o ranṣẹ, emi o si mu Nebukadnessari, ọba Babeli, iranṣẹ mi, emi o si gbe itẹ rẹ̀ kalẹ lori okuta wọnyi, ti emi ti fi pamọ; on o si tẹ itẹ ọla rẹ̀ lori wọn.

11. Nigbati o ba si de, on o kọlu ilẹ Egipti, on o si fi ti ikú, fun ikú: ti igbekun, fun igbekun; ati ti idà, fun idà.

12. Emi o si dá iná kan ni ile awọn oriṣa Egipti; on o si sun wọn, yio si kó wọn lọ; on o si fi ilẹ Egipti wọ ara rẹ̀ laṣọ gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti iwọ̀ aṣọ rẹ̀; yio si jade lati ibẹ lọ li alafia.

13. Yio si fọ́ ere ile-õrùn, ti o wà ni ilẹ Egipti tũtu, yio si fi iná kun ile awọn oriṣa awọn ara Egipti.

Ka pipe ipin Jer 43