Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 43:4-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Bẹ̃ni Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun, ati gbogbo awọn enia, kò gbà ohùn Oluwa gbọ́, lati má gbe ilẹ Juda,

5. Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun, si mu gbogbo iyokù Juda, ti nwọn pada lati gbogbo orilẹ-ède wá, ni ibi ti a ti le wọn si, lati ma gbe ilẹ Juda;

6. Awọn ọkunrin, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọde, ati awọn ọmọbinrin ọba, ati gbogbo enia ti Nebusaradani, balogun iṣọ, ti kù silẹ lọdọ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ati Jeremiah woli, ati Baruku, ọmọ Neriah,

7. Nwọn si wá si ilẹ Egipti: nitori nwọn kò gbà ohùn Oluwa gbọ́: bayi ni nwọn wá si Tafanesi.

8. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá ni Tafanesi, wipe,

9. Mu okuta nla li ọwọ rẹ ki o si fi wọn pamọ sinu amọ̀, ni ile-iná briki ti o wà ni ẹnu-ọ̀na ile Farao ni Tafanesi, li oju awọn ọkunrin Juda.

10. Ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi, pe, wò o, emi o ranṣẹ, emi o si mu Nebukadnessari, ọba Babeli, iranṣẹ mi, emi o si gbe itẹ rẹ̀ kalẹ lori okuta wọnyi, ti emi ti fi pamọ; on o si tẹ itẹ ọla rẹ̀ lori wọn.

11. Nigbati o ba si de, on o kọlu ilẹ Egipti, on o si fi ti ikú, fun ikú: ti igbekun, fun igbekun; ati ti idà, fun idà.

12. Emi o si dá iná kan ni ile awọn oriṣa Egipti; on o si sun wọn, yio si kó wọn lọ; on o si fi ilẹ Egipti wọ ara rẹ̀ laṣọ gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti iwọ̀ aṣọ rẹ̀; yio si jade lati ibẹ lọ li alafia.

13. Yio si fọ́ ere ile-õrùn, ti o wà ni ilẹ Egipti tũtu, yio si fi iná kun ile awọn oriṣa awọn ara Egipti.

Ka pipe ipin Jer 43