Nigbana ni Asariah, ọmọ Hoṣaiah, ati Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn agberaga enia, wi fun Jeremiah pe, Iwọ ṣe eke! Oluwa, Ọlọrun wa, kò ran ọ lati wipe, Ẹ má lọ si Egipti lati ṣatipo nibẹ: