Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 42:7-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. O si ṣe lẹhin ọjọ mẹwa li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá.

8. Nigbana ni o pè Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o wà pẹlu rẹ̀, ati gbogbo awọn enia lati ẹni-kekere titi de ẹni-nla.

9. O si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, sọdọ ẹniti ẹnyin rán mi, lati mu ẹ̀bẹ nyin wá siwaju rẹ̀;

10. Bi ẹnyin o ba gbe ilẹ yi lõtọ, nigbana ni emi o gbe nyin ro emi kì yio si fà nyin lulẹ, emi o si gbìn nyin, emi kì yio si fà nyin tu: nitori emi yi ọkàn pada niti ibi ti emi ti ṣe si nyin.

11. Ẹ má bẹ̀ru ọba Babeli, ẹniti ẹnyin mbẹ̀ru: ẹ máṣe bẹ̀ru rẹ̀, li Oluwa wi: nitori emi wà pẹlu nyin lati ràn nyin lọwọ, ati lati gbà nyin li ọwọ rẹ̀.

12. Emi o si fi ãnu hàn fun nyin, ki on ki o le ṣãnu fun nyin, ki o si mu ki ẹnyin pada si ilẹ nyin.

13. Ṣugbọn bi ẹnyin ba wipe, Awa kì yio gbe ilẹ yi, ti ẹnyin kò si gbà ohùn Oluwa Ọlọrun nyin gbọ́.

14. Wipe, bẹ̃kọ̀; ṣugbọn awa fẹ lọ si ilẹ Egipti, nibiti awa kì yio ri ogun-kogun, ti a kì o si gbọ́ iró fère, ti ebi onjẹ kò ni ipa wa, nibẹ li awa o si mã gbe:

Ka pipe ipin Jer 42