Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 40:7-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Njẹ nigbati gbogbo awọn olori ogun, ti o wà li oko, awọn ati awọn ọkunrin wọn, gbọ́ pe ọba Babeli ti fi Gedaliah, ọmọ Ahikamu, jẹ bãlẹ ni ilẹ na, o si ti fi awọn ọkunrin fun u, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọde, ati ninu awọn talaka ilẹ na, ninu awọn ti a kò kó lọ ni igbekun si Babeli.

8. Nwọn tọ̀ Gedaliah wá ni Mispa, ani Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, ati Johanani, ati Jonatani, awọn ọmọ Karea, ati Seraiah, ọmọ Tanhumeti, ati awọn ọmọ Efai, ara Netofa, ati Jesaniah, ọmọ ara Maaka, awọn ati awọn ọkunrin wọn,

9. Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, si bura fun wọn ati fun awọn ọkunrin wọn, wipe: Ẹ má bẹ̀ru lati sìn awọn ara Kaldea: ẹ gbe ilẹ̀ na, ki ẹ si mã sin ọba Babeli, yio si dara fun nyin.

10. Bi o ṣe ti emi, wò o, emi o ma gbe Mispa, lati sìn awọn ara Kaldea, ti yio tọ wa wá; ṣugbọn ẹnyin ẹ kó ọti-waini jọ, ati eso-igi, ati ororo, ki ẹ si fi sinu ohun-elo nyin, ki ẹ si gbe inu ilu nyin ti ẹnyin ti gbà.

11. Pẹlupẹlu gbogbo awọn ara Juda, ti o wà ni Moabu, ati lãrin awọn ọmọ Ammoni, ati ni Edomu, ati awọn ti o wà ni gbogbo ilẹ wọnni gbọ́ pe, ọba Babeli ti fi iyokù silẹ fun Juda, ati pe o ti fi Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ṣolori wọn;

Ka pipe ipin Jer 40