Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 4:20-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Iparun lori iparun ni a nke; nitori gbogbo ilẹ li o ti parun, lojiji ni agọ mi di ijẹ, pẹlu aṣọ ikele mi ni iṣẹju kan.

21. Yio ti pẹ to ti emi o ri ọpagun, ti emi o si gbọ́ iro fère?

22. Nitori òpe li enia mi, nwọn kò mọ̀ mi; alaimoye ọmọ ni nwọn iṣe, nwọn kò si ni ìmọ: nwọn ni ọgbọ́n lati ṣe ibi, ṣugbọn oye ati ṣe rere ni nwọn kò ni.

23. Mo bojuwo aiye, sa wò o, o wà ni jũju, o si ṣofo; ati ọrun, imọlẹ kò si lara rẹ̀.

24. Mo bojuwo gbogbo oke nla, sa wò o, o warìri ati gbogbo oke kekere mì jẹjẹ.

25. Mo bojuwo, sa wò o, kò si enia kan, pẹlupẹlu gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun sa lọ.

26. Mo bojuwo, sa wò o, Karmeli di aginju, ati gbogbo ilu rẹ̀ li o wó lulẹ, niwaju Oluwa ati niwaju ibinu rẹ̀ gbigbona.

27. Nitori bayi li Oluwa wi pe: Gbogbo ilẹ ni yio di ahoro; ṣugbọn emi kì yio ṣe ipari tan.

28. Nitori eyi ni ilẹ yio ṣe kãnu, ati ọrun loke yio di dudu: nitori emi ti wi i, mo ti pete rẹ̀, emi kì o yi ọkàn da, bẹ̃ni kì o yipada kuro ninu rẹ̀.

29. Gbogbo ilu ni yio sá nitori ariwo awọn ẹlẹṣin ati awọn tafatafa; nwọn o sa lọ sinu igbo; nwọn o si gun ori oke okuta lọ, gbogbo ilu ni a o kọ̀ silẹ, ẹnikan kì yio gbe inu wọn.

30. Ati iwọ, ẹniti o di ijẹ tan, kini iwọ o ṣe? Iwọ iba wọ ara rẹ ni aṣọ òdodó, iwọ iba fi wura ṣe ara rẹ lọṣọ, iwọ iba fi tirõ kun oju rẹ: lasan ni iwọ o ṣe ara rẹ daradara, awọn ayanfẹ rẹ yio kọ̀ ọ silẹ, nwọn o wá ẹmi rẹ.

31. Nitori mo ti gbọ́ ohùn kan bi ti obinrin ti nrọbi, irora bi obinrin ti nbi akọbi ọmọ rẹ̀, ohùn ọmọbinrin Sioni ti npohùnrere ẹkun ara rẹ̀, ti o nnà ọwọ rẹ̀ wipe: Egbé ni fun mi nisisiyi nitori ãrẹ mu mi li ọkàn, nitori awọn apania.

Ka pipe ipin Jer 4