Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 36:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe li ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah ọba Juda, li ọ̀rọ yi tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa wá, wipe,

2. Mu iwe-kiká fun ara rẹ̀, ki o si kọ sinu rẹ̀, gbogbo ọ̀rọ ti emi ti sọ si Israeli, ati si Juda, ati si gbogbo orilẹ-ède, lati ọjọ ti mo ti sọ fun ọ, lati ọjọ Josiah titi di oni yi.

3. O le jẹ pe ile Juda yio gbọ́ gbogbo ibi ti mo pinnu lati ṣe si wọn; ki nwọn ki o le yipada, olukuluku kuro li ọ̀na buburu rẹ̀; ki emi ki o dari aiṣedede wọn ati ẹ̀ṣẹ wọn ji wọn.

4. Nigbana ni Jeremiah pè Baruku, ọmọ Neriah; Baruku si kọ lati ẹnu Jeremiah gbogbo ọ̀rọ Oluwa ti o ti sọ fun u, sori iwe-kiká na.

5. Jeremiah si paṣẹ fun Baruku pe, a se mi mọ: emi kò le lọ si ile Oluwa:

6. Nitorina iwọ lọ, ki o si kà ninu iwe-kika na, ti iwọ kọ lati ẹnu mi wá, ọ̀rọ Oluwa li eti awọn enia ni ile Oluwa li ọjọ ãwẹ: ati pẹlu, iwọ o si kà a li eti gbogbo Juda, ti nwọn jade wá lati ilu wọn.

Ka pipe ipin Jer 36