Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 35:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa li ọjọ Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, wipe:

2. Lọ si ile awọn ọmọ Rekabu, ki o si ba wọn sọ̀rọ, ki o si mu wọn wá si ile Oluwa, si ọkan ninu iyara wọnni, ki o si fun wọn li ọti-waini mu.

3. Nigbana ni mo mu Jaasaniah, ọmọ Jeremiah, ọmọ Habasiniah, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo ile awọn ọmọ Rekabu;

4. Mo si mu wọn wá si ile Oluwa, sinu iyara awọn ọmọ Hanani, ọmọ Igdaliah, enia Ọlọrun, ti o wà lẹba iyara awọn ijoye, ti o wà li oke iyara Maaseiah, ọmọ Ṣallumu, olutọju ẹnu-ọ̀na,

5. Mo si gbe ìkoko ti o kún fun ọti-waini pẹlu ago, ka iwaju awọn ọmọ ile Rekabu, mo si wi fun wọn pe: Ẹ mu ọti-waini.

6. Ṣugbọn nwọn wipe, Awa kì yio mu ọti-waini, nitori Jonadabu, ọmọ Rekabu, baba wa, paṣẹ fun wa pe: Ẹnyin kò gbọdọ mu ọti-waini, ẹnyin ati awọn ọmọ nyin lailai.

Ka pipe ipin Jer 35