Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 34:19-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Awọn ijoye Juda, ati awọn ijoye Jerusalemu, awọn ìwẹfa, ati awọn alufa, ati gbogbo enia ilẹ na, ti o kọja lãrin ipin mejeji ẹgbọrọ malu na;

20. Emi o fi wọn le ọwọ awọn ọta wọn, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn: okú wọn yio si jẹ onjẹ fun awọn ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun awọn ẹranko igbẹ.

21. Ati Sedekiah, ọba Juda, ati awọn ijoye rẹ̀ li emi o fi le ọwọ awọn ọta wọn, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn, ati le ọwọ ogun ọba Babeli, ti o ṣi lọ kuro lọdọ nyin.

22. Wò o, emi o paṣẹ, li Oluwa wi: emi o si mu wọn pada si ilu yi; nwọn o si ba a jà, nwọn o si kó o, nwọn o si fi iná kún u: emi o si ṣe ilu Juda li ahoro laini olugbe.

Ka pipe ipin Jer 34