Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 26:13-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Njẹ nisisiyi, ẹ tun ọ̀na nyin ati iṣe nyin ṣe, ki ẹ si gbọ́ ohùn Oluwa Ọlọrun nyin; Oluwa yio si yi ọkàn rẹ̀ pada niti ibi ti o sọ si nyin.

14. Bi o ṣe ti emi, sa wò o, emi mbẹ li ọwọ nyin: ẹ ṣe si mi, gẹgẹ bi o ti dara ti o si yẹ loju nyin.

15. Sibẹ, ẹ mọ̀ eyi daju pe, bi ẹ ba pa mi, mimu ni ẹnyin o mu ẹ̀jẹ alaiṣẹ wá sori nyin ati sori ilu yi, ati sori awọn olugbe rẹ̀: nitori li otitọ Oluwa li o rán mi si nyin lati sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi li eti nyin.

16. Nigbana ni awọn ijoye ati gbogbo enia sọ fun awọn alufa ati awọn woli pe, ọkunrin yi kò yẹ lati kú; nitoriti o sọ̀rọ fun wa li orukọ Oluwa, Ọlọrun wa.

17. Awọn ọkunrin kan ninu awọn àgba na si dide, nwọn si sọ fun gbogbo ijọ enia wipe:

18. Mikah, ara Moraṣi, ṣe woli li ọjọ Hesekiah, ọba Juda, o si wi fun gbogbo enia Juda pe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: a o tulẹ Sioni fun oko, Jerusalemu yio di òkiti alapa, ati oke ile yi gẹgẹ bi ibi giga igbo.

19. Njẹ, Hesekiah, ọba Juda, ati gbogbo Juda ha pa a bi? Ẹ̀ru Oluwa kò ha bà a, kò ha bẹ Oluwa bi? Oluwa si yi ọkàn pada niti ibi ti o ti sọ si wọn; Bayi li awa iba ṣe mu ibi nla wá sori ẹmi wa?

20. Ọkunrin kan si wà ẹ̀wẹ, ti o sọ asọtẹlẹ ni orukọ Oluwa, ani Urijah, ọmọ Ṣemaiah, ara Kirjatjearimu, ti o sọ asọtẹlẹ si ilu yi, ati si ilẹ yi, gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ Jeremiah.

21. Ati nigbati Jehoiakimu, ọba, pẹlu gbogbo ọkunrin alagbara rẹ̀, ati awọn ijoye gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ọba nwá a lati pa; ṣugbọn nigbati Urijah gbọ́, o bẹ̀ru, o salọ o si wá si Egipti.

22. Jehoiakimu, ọba, si rán enia lọ si Egipti, ani Elnatani, ọmọ Akbori ati enia miran pẹlu rẹ̀ lọ si Egipti.

23. Nwọn si mu Urijah lati Egipti tọ Jehoiakimu ọba wá; ẹni ti o fi idà pa a, o si sọ okú rẹ̀ sinu isa-okú awọn enia lasan.

24. Bẹ̃ni ọwọ Ahikamu, ọmọ Safani mbẹ pẹlu Jeremiah, ki nwọn ki o má ba fi i le awọn enia lọwọ lati pa.

Ka pipe ipin Jer 26