Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 26:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NI ibẹrẹ ijọba Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, ni ọ̀rọ yi ti ọdọ Oluwa wá wipe;

2. Bayi li Oluwa wi, Duro ni àgbala ile Oluwa, ki o si sọ fun gbogbo ilu Juda ti o wá lati sìn ni ile Oluwa gbogbo ọ̀rọ ti mo pa laṣẹ fun ọ lati sọ fun wọn: máṣe ke ọ̀rọ kanṣoṣo kù:

3. Bi o ba jẹ pe nwọn o gbọ́, ti olukuluku yio yipada kuro li ọ̀na buburu rẹ̀, ki emi ki o le yi ọkàn pada niti ibi ti emi rò lati ṣe si wọn, nitori iṣe buburu wọn.

4. Iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi: bi ẹnyin kì yio feti si mi lati rin ninu ofin mi, ti emi ti gbe kalẹ niwaju nyin.

5. Lati gbọ́ ọ̀rọ awọn ọmọ-ọdọ mi, awọn woli, ti emi rán si nyin, ti mo ndide ni kutukutu, ti mo rán wọn; ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́.

6. Emi o si ṣe ile yi bi Ṣilo, emi o si ṣe ilu yi ni ifibu si gbogbo orilẹ-ède aiye.

7. Nigbana ni awọn alufa, ati awọn woli, ati gbogbo enia gbọ́, bi Jeremiah ti nsọ ọ̀rọ wọnyi ni ile Oluwa.

8. O si ṣe nigbati Jeremiah pari gbogbo ọ̀rọ ti Oluwa paṣẹ fun u lati sọ fun gbogbo enia, nigbana ni awọn alufa, ati awọn woli, ati gbogbo enia di i mu wipe, kikú ni iwọ o kú!

9. Ẽṣe ti iwọ sọ asọtẹlẹ li orukọ Oluwa wipe, Ile yi yio dabi Ṣilo, ati ilu yi yio di ahoro laini olugbe? Gbogbo enia kojọ pọ̀ tì Jeremiah ni ile Oluwa.

10. Nigbati awọn ijoye Juda gbọ́ nkan wọnyi, nwọn jade lati ile ọba wá si ile Oluwa, nwọn si joko li ẹnu-ọ̀na titun ile Oluwa.

11. Awọn alufa ati awọn woli wi fun awọn ijoye, ati gbogbo enia pe, ọkunrin yi jẹbi ikú nitoriti o sọ asọtẹlẹ si ilu yi, bi ẹnyin ti fi eti nyin gbọ́.

12. Nigbana ni Jeremiah wi fun awọn ijoye ati gbogbo enia pe, Oluwa rán mi lati sọ asọtẹlẹ gbogbo ọ̀rọ ti ẹnyin gbọ́, si ile yi ati si ilu yi.

13. Njẹ nisisiyi, ẹ tun ọ̀na nyin ati iṣe nyin ṣe, ki ẹ si gbọ́ ohùn Oluwa Ọlọrun nyin; Oluwa yio si yi ọkàn rẹ̀ pada niti ibi ti o sọ si nyin.

14. Bi o ṣe ti emi, sa wò o, emi mbẹ li ọwọ nyin: ẹ ṣe si mi, gẹgẹ bi o ti dara ti o si yẹ loju nyin.

Ka pipe ipin Jer 26