Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 25:28-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Yio si ṣe, bi nwọn ba kọ̀ lati gba ago lọwọ rẹ lati mu, ni iwọ o si wi fun wọn pe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ni mimu ẹnyin o mu!

29. Sa wò o, nitori ti emi bẹrẹ si imu ibi wá sori ilu na ti a pè li orukọ mi, ẹnyin fẹ ijẹ alaijiya? ẹnyin kì yio ṣe alaijiya: nitori emi o pè fun idà sori gbogbo olugbe aiye, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

30. Njẹ iwọ sọ asọtẹlẹ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun wọn, ki o si wi fun wọn pe, Oluwa yio kọ lati oke wá, yio si fọ ohùn rẹ̀ lati ibugbe rẹ̀ mimọ́, ni kikọ, yio kọ sori ibugbe rẹ̀, yio pariwo sori gbogbo olugbe aiye, bi awọn ti ntẹ ifunti.

31. Igbe kan yio wá titi de opin ilẹ aiye; nitori Oluwa ni ijà ti yio ba awọn orilẹ-ède ja, yio ba gbogbo ẹran-ara wijọ, yio fi awọn oluṣe-buburu fun idà, li Oluwa wi.

32. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, sa wò o, ibi yio jade lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, ìji nlanla yio ru soke lati agbegbe aiye.

33. Awọn ti Oluwa pa yio wà li ọjọ na lati ipẹkun kini aiye titi de ipẹkun keji aiye, a kì yio ṣọ̀fọ wọn, a kì yio ko wọn jọpọ, bẹ̃ni a kì yio sin wọn, nwọn o di àtan lori ilẹ.

34. Ke! ẹnyin oluṣọ-agutan! ki ẹ si sọkun! ẹ fi ara nyin yilẹ ninu ẽru, ẹnyin ọlọla agbo-ẹran! nitori ọjọ a ti pa nyin ati lati tú nyin ka pe, ẹnyin o si ṣubu bi ohun-elo iyebiye.

35. Sisa kì yio si fun awọn oluṣọ-agutan, bẹ̃ni asalà kì yio si fun awọn ọlọla agbo-ẹran.

36. Ohùn ẹkun awọn oluṣọ-agutan, ati igbe awọn ọlọla agbo-ẹran li a o gbọ́: nitori Oluwa bà papa-oko tutu wọn jẹ.

37. Ibùgbe alafia li o di ahoro, niwaju ibinu kikan Oluwa.

38. O ti fi pantiri rẹ̀ silẹ bi kiniun nitori ti ilẹ wọn di ahoro, niwaju ibinu idà aninilara, ati niwaju ibinu kikan rẹ̀.

Ka pipe ipin Jer 25