Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 25:12-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Yio si ṣe, nigbati ãdọrin ọdun ba pari tan, li emi o bẹ̀ ọba Babeli, ati orilẹ-ède na, ati ilẹ awọn ara Kaldea wò, nitori ẹ̀ṣẹ wọn; li Oluwa wi, emi o si sọ ọ di ahoro titi lai.

13. Emi o si mu gbogbo ọ̀rọ mi wá sori ilẹ na, ti mo ti sọ si i: ani gbogbo eyiti a ti kọ sinu iwe yi, eyiti Jeremiah ti sọtẹlẹ si gbogbo orilẹ-ède.

14. Nitoriti awọn wọnyi pẹlu yio mu ki orilẹ-ède pupọ, ati awọn ọba nla sìn wọn: emi o san a fun wọn gẹgẹ bi iṣe wọn ati pẹlu gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wọn.

15. Nitori bayi ni Oluwa Ọlọrun Israeli wi fun mi: Gba ago ọti-waini ibinu mi yi kuro lọwọ mi, ki o si jẹ ki gbogbo orilẹ-ède ti emi o rán ọ si, mu u.

16. Ki nwọn mu, ki nwọn si ma ta gbọ̀ngbọn, ki nwọn si di aṣiwere, nitori idà ti emi o rán si ãrin wọn.

17. Nigbana ni mo gba ago na li ọwọ Oluwa, emi si jẹ ki gbogbo orilẹ-ède, ti Oluwa rán mi si, mu u.

18. Ani Jerusalemu ati ilu Juda wọnni, ati awọn ọba wọn pẹlu awọn ijoye, lati sọ wọn di ahoro, idãmu, ẹsin, ati egún, gẹgẹ bi o ti ri loni.

19. Farao, ọba Egipti, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo enia rẹ̀.

20. Ati gbogbo awọn enia ajeji, ati gbogbo ọba ilẹ Usi, gbogbo ọba ilẹ Filistia, ati Aṣkeloni, ati Gasa, ati Ekroni, ati awọn iyokù Aṣdodi,

21. Edomu, ati Moabu, ati awọn ọmọ Ammoni,

22. Ati gbogbo awọn ọba Tire, ati gbogbo awọn ọba Sidoni, ati awọn ọba erekuṣu wọnni ti mbẹ ni ikọja okun,

23. Dedani, ati Tema, ati Busi, ati gbogbo awọn ti nda òṣu.

24. Ati gbogbo awọn ọba Arabia, pẹlu awọn ọba awọn enia ajeji ti ngbe inu aginju.

25. Ati gbogbo awọn ọba Simri, ati gbogbo awọn ọba Elamu, ati gbogbo awọn ọba Medea.

26. Ati gbogbo awọn ọba ariwa, ti itosi ati ti ọ̀na jijin, ẹnikini pẹlu ẹnikeji rẹ̀, ati gbogbo ijọba aiye, ti mbẹ li oju aiye, ọba Ṣeṣaki yio si mu lẹhin wọn.

27. Iwọ o si wi fun wọn pe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, Ẹ mu, ki ẹ si mu amuyo, ki ẹ bì, ki ẹ si ṣubu, ki ẹ má si le dide mọ́, nitori idà ti emi o rán sãrin nyin.

28. Yio si ṣe, bi nwọn ba kọ̀ lati gba ago lọwọ rẹ lati mu, ni iwọ o si wi fun wọn pe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ni mimu ẹnyin o mu!

Ka pipe ipin Jer 25