Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 25:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá nitori gbogbo enia Juda, li ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọbà Juda, ti iṣe ọdun ikini Nebukadnessari, ọba Babeli.

2. Eyi ti Jeremiah, woli, sọ fun gbogbo enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu wipe:

3. Lati ọdun kẹtala Josiah, ọmọ Amoni, ọba Juda, titi di oni-oloni, eyini ni, ọdun kẹtalelogun, ọ̀rọ Oluwa ti tọ mi wá, emi si ti sọ fun nyin, emi ndide ni kutukutu, emi nsọ, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i.

4. Oluwa si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli si nyin, o ndide ni kutukutu lati rán wọn, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i, bẹ̃ni ẹnyin kò tẹ eti nyin silẹ lati gbọ́.

5. Wipe, ẹ sa yipada, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ati kuro ni buburu iṣe nyin, ẹnyin o si gbe ilẹ ti Oluwa ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin lai ati lailai.

6. Ki ẹ má si tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati ma sìn wọn, ati lati ma foribalẹ fun wọn, ki ẹ má si ṣe fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu, emi kì yio si ṣe nyin ni ibi.

7. Ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́ temi, li Oluwa wi, ki ẹnyin le fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu si ibi ara nyin.

Ka pipe ipin Jer 25