orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 24 Yorùbá Bibeli (YCE)

Apẹ̀rẹ̀ Èso Ọ̀pọ̀tọ́ Meji

1. SI wò o, Oluwa fi agbọn eso-ọ̀pọtọ meji hàn mi, ti a gbe kalẹ niwaju ile Oluwa, lẹhin igbati Nebukadnessari, ọba Babeli, ti mu Jekoniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, ni ìgbekun pẹlu awọn olori Juda, pẹlu awọn gbẹna-gbẹna, ati awọn alagbẹdẹ, lati Jerusalemu, ti o si mu wọn wá si Babeli.

2. Agbọn ikini ni eso-ọ̀pọtọ daradara jù, gẹgẹ bi eso ọ̀pọtọ ti o tetekọ pọ́n: agbọn ekeji ni eso-ọ̀pọtọ ti o buruju, ti a kò le jẹ, bi nwọn ti buru tó.

3. Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, Kini iwọ ri, Jeremiah? Emi wipe, Eso-ọ̀pọtọ, eyi ti o dara, dara jù, ati eyi ti o buru, buru jù, tobẹ̃ ti a kò le jẹ ẹ, nitori nwọn buru jù.

4. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe,

5. Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi; Gẹgẹ bi eso-ọ̀pọtọ daradara wọnyi, bẹ̃li emi o fi oju rere wò awọn ìgbekun Juda, ti emi ran jade kuro ni ibi yi lọ si ilẹ awọn ara Kaldea.

6. Emi o si kọju mi si wọn fun rere, emi o si mu wọn pada wá si ilẹ yi, emi o gbe wọn ró li aitun wó wọn lulẹ, emi o gbìn wọn, li aitun fà wọn tu.

7. Emi o si fun wọn li ọkàn lati mọ̀ mi, pe, Emi li Oluwa, nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nitoripe nwọn o fi gbogbo ọkàn wọn yipada si mi.

8. Ati gẹgẹ bi eso-ọ̀pọtọ biburujù ti a kò le jẹ, nitoriti nwọn burujù, bayi li Oluwa wi, Bẹ̃ gẹgẹ ni emi o ṣe Sedekiah, ọba Juda, ati awọn ijoye rẹ̀, ati awọn ti o kù ni Jerusalemu, ati awọn iyokù ni ilẹ yi ati awọn ti ngbe ilẹ Egipti.

9. Emi o fi wọn fun iwọsi ati fun ibi ninu gbogbo ijọba aiye, lati di ìtiju, owe, ẹsin, ati ẹ̀gan ni ibi gbogbo, ti emi o le wọn si.

10. Emi o si rán idà, ìyan, ati ajakalẹ-arun, si ãrin wọn, titi nwọn o fi parun kuro ni ilẹ eyi ti emi fi fun wọn ati fun awọn baba wọn.