Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 21:7-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Lẹhin eyi, li Oluwa wi, emi o fi Sedekiah, ọba Juda, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn enia, ati awọn ti o kù ni ilu yi lọwọ ajakalẹ-àrun ati lọwọ idà, ati lọwọ ìyan; emi o fi wọn le Nebukadnessari, ọba Babeli lọwọ, ati le ọwọ awọn ọta wọn, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn: yio si fi oju idà pa wọn; kì yio da wọn si, bẹ̃ni kì yio ni iyọ́nu tabi ãnu.

8. Ati fun enia yi ni ki iwọ ki o wipe, Bayi li Oluwa wi; Sa wò o, emi fi ọ̀na ìye ati ọ̀na ikú lelẹ niwaju nyin.

9. Ẹniti o ba joko ninu ilu yi, yio ti ipa idà kú, ati nipa ìyan ati nipa àjakalẹ-àrun: ṣugbọn ẹniti o ba jade ti o si ṣubu si ọwọ awọn ara Kaldea ti o dó tì nyin, yio yè, ẹmi rẹ̀ yio si dabi ijẹ fun u.

10. Nitori emi ti yi oju mi si ilu yi fun ibi, kì isi iṣe fun rere, li Oluwa wi: a o fi i le ọba Babeli lọwọ, yio fi iná kun u.

11. Ati fun ile ọba Juda; Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa:

12. Ile Dafidi, Bayi li Oluwa wi, Mu idajọ ṣẹ li owurọ, ki o si gba ẹniti a lọ lọwọ gba kuro li ọwọ aninilara, ki ibinu mi ki o má ba jade bi iná, ki o má si jo ti kì o si ẹniti yio pa a, nitori buburu iṣe nyin.

13. Wò o, Emi doju kọ nyin, olugbe afonifoji, ati ti okuta pẹtẹlẹ, li Oluwa wi, ẹnyin ti o wipe, Tani yio kọlu wa? ati tani yio wọ̀ inu ibugbe wa?

14. Ṣugbọn emi o jẹ nyin niya gẹgẹ bi eso iṣe nyin, li Oluwa wi; emi o si da iná ninu igbo rẹ ki o le jo gbogbo agbegbe rẹ.

Ka pipe ipin Jer 21