Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 21:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa nigbati Sedekiah, ọba, ran Paṣuru, ọmọ Melkiah, ati Sefaniah, ọmọ Maaseah, alufa, wipe,

2. Bère, emi bẹ ọ, lọdọ Oluwa fun wa; nitori Nebukadnessari, ọba Babeli, ṣi ogun tì wa; bọya bi Oluwa yio ba wa lò gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ iyanu rẹ̀, ki on ki o le lọ kuro lọdọ wa.

3. Nigbana ni Jeremiah wi fun wọn pe, Bayi li ẹnyin o wi fun Sedekiah.

4. Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi: wõ, emi o yi ihamọra ogun ti o wà ni ọwọ nyin pada, eyiti ẹnyin nfi ba ọba Babeli, ati awọn ara Kaldea jà, ti o dotì nyin lẹhin odi, emi o kó wọn jọ si ãrin ilu yi.

5. Emi tikarami yio fi ọwọ ninà ati apa lile ba nyin jà, pẹlupẹlu ni ibinu, ati ni ikannu pẹlu ibinu nla.

6. Emi o si pa awọn olugbe ilu yi, enia pẹlu ẹranko, nwọn o ti ipa àjakalẹ-arun nlanla kú.

7. Lẹhin eyi, li Oluwa wi, emi o fi Sedekiah, ọba Juda, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn enia, ati awọn ti o kù ni ilu yi lọwọ ajakalẹ-àrun ati lọwọ idà, ati lọwọ ìyan; emi o fi wọn le Nebukadnessari, ọba Babeli lọwọ, ati le ọwọ awọn ọta wọn, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn: yio si fi oju idà pa wọn; kì yio da wọn si, bẹ̃ni kì yio ni iyọ́nu tabi ãnu.

8. Ati fun enia yi ni ki iwọ ki o wipe, Bayi li Oluwa wi; Sa wò o, emi fi ọ̀na ìye ati ọ̀na ikú lelẹ niwaju nyin.

9. Ẹniti o ba joko ninu ilu yi, yio ti ipa idà kú, ati nipa ìyan ati nipa àjakalẹ-àrun: ṣugbọn ẹniti o ba jade ti o si ṣubu si ọwọ awọn ara Kaldea ti o dó tì nyin, yio yè, ẹmi rẹ̀ yio si dabi ijẹ fun u.

10. Nitori emi ti yi oju mi si ilu yi fun ibi, kì isi iṣe fun rere, li Oluwa wi: a o fi i le ọba Babeli lọwọ, yio fi iná kun u.

Ka pipe ipin Jer 21