Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 2:22-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Nitori iwọ iba wẹ ara rẹ ni ẽru, ki o si mu ọṣẹ pupọ, ẽri ni ẹ̀ṣẹ rẹ niwaju mi sibẹsibẹ, li Oluwa Ọlọrun wi.

23. Bawo li o ṣe wipe, emi kò ṣe alaimọ́, emi kò tọpa Baalimu? wò ọ̀na rẹ li afonifoji, mọ̀ ohun ti iwọ ti ṣe, iwọ dabi abo ibakasiẹ ayasẹ̀ ti nrin ọ̀na rẹ̀ ka.

24. Kẹtẹkẹtẹ igbẹ ti ima gbe aginju, ninu ifẹ ọkàn rẹ̀ ti nfa ẹfufu, li akoko rẹ̀, tani le yi i pada? gbogbo awọn ti nwá a kiri kì yio da ara wọn li agara, nwọn o ri i li oṣu rẹ̀.

25. Da ẹsẹ̀ rẹ duro ni aiwọ bàta, ati ọfun rẹ ninu ongbẹ: ṣugbọn iwọ wipe, lasan ni! bẹ̃kọ, nitoriti emi ti fẹ awọn alejo, awọn li emi o tọ̀ lẹhin.

26. Gẹgẹ bi oju ti itì ole nigbati a ba mu u, bẹ̃li oju tì ile Israeli; awọn ọba wọn, ijoye wọn, alufa wọn, ati woli wọn pẹlu.

27. Ti nwọn wi fun igi pe, Iwọ ni baba mi; ati fun okuta pe, iwọ li o bi mi. Nitori nwọn ti yi ẹ̀hìn wọn pada si mi kì iṣe iwaju wọn: ṣugbọn ni igba ipọnju wọn, nwọn o wipe, Dide, ki o gbani.

28. Njẹ nibo li awọn ọlọrun rẹ wà, ti iwọ ti da fun ara rẹ? jẹ ki nwọn ki o dide, bi nwọn ba le gba ọ nigba ipọnju rẹ, nitori bi iye ilu rẹ, bẹ̃li ọlọrun rẹ, iwọ Juda.

29. Ẽṣe ti ẹnyin o ba mi jà? gbogbo nyin li o ti rufin mi, li Oluwa wi.

30. Lasan ni mo lù ọmọ nyin, nwọn kò gbà ibawi, idà ẹnyin tikara nyin li o pa awọn woli bi kiniun apanirun.

31. Iran enia yi, ẹ kiyesi ọ̀rọ Oluwa. Emi ha ti di aginju si Israeli bi? tabi ilẹ okunkun biribiri, ẽṣe ti enia mi wipe, awa nrin kakiri, awa kì yio tọ̀ ọ wá mọ.

32. Wundia le gbagbe ohun ọṣọ rẹ̀, tabi iyawo ọjá-ọṣọ rẹ̀? ṣugbọn enia mi ti gbagbe mi li ọjọ ti kò ni iye.

33. Ẽṣe ti iwọ tun ọ̀na rẹ ṣe lati wá ifẹ rẹ? nitorina iwọ ṣe kọ́ awọn obinrin buburu li ọ̀na rẹ.

34. Pẹlupẹlu ẹjẹ ẹmi awọn talaka ati alaiṣẹ mbẹ lara aṣọ rẹ, iwọ kò ri wọn nibi irunlẹ wọle, ṣugbọn lara gbogbo wọnyi.

Ka pipe ipin Jer 2