Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 19:6-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nitorina, sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, a kì yio pe orukọ ibi yi ni Tofeti mọ, tabi afonifoji ọmọ Hinnomu, ṣugbọn Afonifoji ipakupa.

7. Emi o sọ igbimọ Juda ati Jerusalemu di asan ni ibi yi; emi o mu ki nwọn ki o ṣubu niwaju ọta wọn, ati lọwọ awọn ti o nwá ẹmi wọn, okú wọn ni a o fi fun ẹiyẹ oju-ọrun, ati ẹranko ilẹ fun onjẹ.

8. Emi o si sọ ilu yi di ahoro, ati ẹ̀gan, ẹnikẹni ti o ba nkọja lọ nibẹ yio dãmu, yio si poṣe nitori gbogbo ìna rẹ̀.

9. Emi o si mu ki nwọn ki o jẹ ẹran-ara awọn ọmọkunrin wọn, ati ẹran-ara awọn ọmọbinrin wọn, ati ẹnikini wọn yio jẹ ẹran-ara ẹnikẹji ni igba idoti ati ihamọ, ti awọn ọta wọn, ati awọn ti o nwá ẹmi wọn yio ha wọn mọ.

10. Nigbana ni iwọ o fọ igo na li oju awọn ti o ba ọ lọ.

11. Ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: Bẹ̃ gẹgẹ li emi o fọ enia yi ati ilu yi, bi a ti ifọ ohun-èlo amọkoko, ti ẹnikan kò le tun ṣe mọ, nwọn o si sin wọn ni Tofeti, nitoriti aye kò si lati sinkú.

12. Bayi li emi o ṣe si ibi yi, li Oluwa wi, ati si olugbe inu rẹ̀, emi o tilẹ ṣe ilu yi bi Tofeti:

13. Gbogbo ile Jerusalemu ati ile awọn ọba Juda ni a o sọ di alaimọ́ bi Tofeti, gbogbo ile wọnni, lori orule eyiti a ti sun turari fun ogun ọrun, ti a si ru ẹbọ mimu fun ọlọrun miran.

14. Nigbana ni Jeremiah wá si Tofeti, nibiti Oluwa ti rán a lati sọ asọtẹlẹ; o si duro ni àgbala ile Oluwa; o si wi fun gbogbo awọn enia pe,

15. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi; Sa wò o, emi o mu wá sori ilu yi, ati sori ileto rẹ̀ gbogbo ibi ti mo ti sọ si i, nitori ti nwọn ti wà ọrun kì, ki nwọn ki o má bà gbọ́ ọ̀rọ mi.

Ka pipe ipin Jer 19